Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 33:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tó ń sán fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.”

4. Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀sọ́ rẹ̀.

5. Nítorí Olúwa ti wí fún Mósè pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ènìyàn ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí èmi bá lè wa sí àárin yín ni ìsẹ́jú kan, èmi lè pa yín run. Ní sinsin yìí, bọ́ ohun ọ̀sọ́ rẹ kúrò, èmi yóò sì gbèrò ohun tí èmi yóò se pẹ̀lú rẹ.’ ”

6. Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Hórébù.

7. Mósè máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bèrè Olúwa yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó.

8. Nígbàkúgbà tí Mósè bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mósè títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà.

9. Bí Mósè ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ̀n àwọ̀ọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mósè.

10. Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọ̀ọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.

11. Olúwa máa ń bá Mósè sọ̀rọ̀ lójúkorojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mósè yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Jósúà ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Núnì kò fi àgọ́ sílẹ̀.

12. Mósè sọ fún Olúwa pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́ nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojú rere mi pẹ̀lú.’

13. Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́, kí n sì le máa wá ojú rere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀ èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”

14. Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.”

Ka pipe ipin Ékísódù 33