Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 33:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà náà ni, Mósè wí fún-un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má se rán wa gòkè láti ìhín lọ.

16. Báwo ni ẹnìkẹ́ni yóò se mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”

17. Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti bèrè, nítorí inú mi dún sí o, èmi sì mọ̀ ọ́ nípa orúkọ rẹ̀.”

18. Mósè sì wí pé “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.”

19. Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ire mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò sàánú fún ẹni tí èmi yóò sàánú fún, èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún.

20. Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ẹnìkan tó rí mi, tí ó lè yè.”

21. Olúwa sì wí pé, “Ibì kan wà lẹ́gbẹ̀ ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta.

Ka pipe ipin Ékísódù 33