Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 33:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Éjíbítì wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí èmi ti pinnu ní ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ.’

2. Èmi yóò rán ańgẹ́lì ṣáájú yín, èmi yóò sì lé àwọn Kénánì, àwọn ará Ámórì, àwọn ará Hítì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífì àti àwọn ará Jébúsì jáde.

3. Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tó ń sán fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.”

4. Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀sọ́ rẹ̀.

5. Nítorí Olúwa ti wí fún Mósè pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ènìyàn ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí èmi bá lè wa sí àárin yín ni ìsẹ́jú kan, èmi lè pa yín run. Ní sinsin yìí, bọ́ ohun ọ̀sọ́ rẹ kúrò, èmi yóò sì gbèrò ohun tí èmi yóò se pẹ̀lú rẹ.’ ”

6. Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Hórébù.

7. Mósè máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bèrè Olúwa yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó.

Ka pipe ipin Ékísódù 33