Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 3:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mósè ń sọ́ agbo ẹran Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Mídíánì. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jínjìn nínú ihà. Ó dé Hórébù, òkè Ọlọ́run.

2. Níbẹ̀ ni ańgẹ́lì Olúwa ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́ iná ti ń jó láàrin igbó. Mósè rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run

3. Nígbà náà ni Mósè sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”

4. Nígbà tí Olúwa rí i pe Mósè ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárin igbó náà, “Mósè! Mósè!!”Mósè sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nì yìí.”

5. Ọlọ́run sì wí fún Mósè pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.”

6. Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù.” Nítorí ìdí èyí, Mósè fi ojú rẹ̀ pamọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti wo ojú Ọlọ́run.

7. Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Éjíbítì, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára.

8. Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kénánì, Hétì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì.

Ka pipe ipin Ékísódù 3