Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 29:22-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, iwe méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́).

23. Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan.

24. Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.

25. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa, ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa.

26. Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Árónì, ìwọ yóò si fín-in ni ẹbọ fínfín níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.

27. “Ìwọ yóò sì yà igẹ̀ ẹbọ fínfìn náà sí mímọ́, àti ìtan ẹbọ àgbésọ-sókè, tí pa fi tí a sì gbésọ-sókè nínú àgbò ìyàsímímọ̀ náà, àní nínú èyí tíí ṣe Árónì àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀.

28. Èyí ni yóò sì máa se ìpín ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à-gbé-sọ-sókè ni ẹbọ tí yóò sìṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò máa se sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.

29. “Asọ mímọ́ Árónì yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́.

30. Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje.

31. “Ìwọ yóò sì mú àgbò fún ìyàsímímọ́, ìwọ yóò sì bọ ẹran wá ní ibi mímọ́ kan.

32. Ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ ni Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ti jẹ ẹran àgbò náà àti àkàrà náà tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀.

33. Wọn yóò sì jẹ nǹkan wọ̀nyí èyí tí a fi se ètùtù náà fún ìyàsímímọ́ àti ìsọdimímọ́ wọn. Ṣùgbọ́n kò ní sí ẹlòmíràn ti yóò le è jẹ wọ́n, nítorí pé mímọ́ ni.

34. Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn. A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni.

35. “Bàyìí ni ìwọ yóò sìṣe fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ohun gbogbo ti mo paláṣẹ fún ọ, ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi yà wọ́n sí mímọ́.

36. Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún-un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́.

37. Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́. Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohúnkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn-án yóò jẹ́ mímọ́.

38. “Èyí ni ìwọ yóò máa fi rúbọ ní orí pẹpẹ náà: Òdọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé.

39. Odọ àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rúbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́ Àgùntàn èkejì ní àṣálẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 29