Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 27:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ìwọ yóò sí ṣe òpó igi kaṣíà fún pẹpẹ náà, kí o sì bò ó pẹ̀lú idẹ.

7. A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú.

8. Ìwọ yóò síṣe pẹpẹ náà ni oníhò nínú. Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fi hàn ọ́ ní orí òkè.

9. “Ìwọ yóò sí ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúsù gbọ́dọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́,

10. pẹ̀lú ogún (20) òpó àti ogún (20) ihò itẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú.

11. Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun (20) òpó àti ogún ihò itẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.

12. “Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá.

13. Ní ìhà ìlà oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógun ní fífẹ̀,

14. Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,

Ka pipe ipin Ékísódù 27