Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 25:27-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Òrùka náà ko gbọdọ̀ jìnnà sí etí rẹ̀, kí ó lè gbá òpó mú nígbà tí a bá ń gbé tábìlì náà.

28. Fi igi kaṣíà ṣe òpó, fi wúrà bò wọ́n, kí o sì máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.

29. Fi ojúlówó wúrà se àwo àti ṣíbí rẹ̀, kí o sì ṣe àwokòtò àti ago pẹ̀lú fún dída ọrẹ jáde.

30. Gbé àkàrà ìfihàn sí orí tabílì yìí, kí ó le wà ní iwájú mi ni gbogbo ìgbà.

31. “Mú ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, kí o sì fi ṣe ọ̀pá fìtílà, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀.

32. Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì.

33. Kọ́ọ̀bù mẹ́ta tí a se bí òdòdó alímọ́ńdì tí ó sọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni apá kan, mẹ́ta yóò sì wà ní apá kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà.

34. Ní ara ọ̀pá fìtílà ni kọ́ọ̀bù mẹ́rin ti a se gẹ́gẹ́ bí òdòdó alímọńdì ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà.

35. Ìṣọ kan yóò wà lábẹ́ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, ìṣọ kejì lábẹ́ ẹ̀ka méjì kejì, ìṣọ kẹta ní abẹ́ ẹ̀ka mẹ́ta kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀.

36. Ìṣọ àti ẹ̀ka yóò di ara kan náà pẹ̀lú òpó fìtílà ti a fi ojúlówó wúrà ti a lù ṣe.

37. “Nígbà náà ni ìwọ yóò se fítílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn bá a lè tan iná sí iwájú rẹ̀.

38. Ike ọ̀pá àbẹ́là àti ọpọ́n agogo gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi ojúlówó wúrà ṣe.

Ka pipe ipin Ékísódù 25