Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 25:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ṣe kérúbù kan sí igun kìn-ín-ní àti kérúbù kejì sí igun kejì kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì.

20. Apá àwọn kérúbù náà yóò wà ní gbígbé sókè, tí wọn yóò sì fi apá wọn se ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́.

21. Gbé ọmọrí orí àpótí ẹ̀rí kí o sì fi ẹ̀rí èyí tí èmí yóò fi fún ọ sínú àpótí ẹ̀rí.

22. Níbẹ̀, ni òkè ìtẹ́, ní àárin kérúbù méjèèjì ti ó wà ni orí àpótí ẹ̀rí ni èmi yóò ti pàdé rẹ, ti èmi yóò sì fún ọ ní àwọn òfin mi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

23. “Fi igi kaṣíà kan tábílì: ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní gíga.

24. Kí o fi ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì mọ wúrà yíká.

25. Bákan náà, mọ etí rẹ̀ yíká pẹ̀lú wúrà níwọ̀n fífẹ ìbúwọ́, kí o sì fi wúrà mímọ́ sí ibí orúka rẹ.

Ka pipe ipin Ékísódù 25