Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 21:19-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ẹni tó lu ẹnìkejì rẹ̀ kò ní ní ẹ̀bi, níwọ̀n ìgbà ti ẹni tí a lù bá ti lè dìde, tí ó sì lé è fi ọ̀pá ìtilẹ̀ ní ọwọ rẹ̀ rìn káàkiri. Ẹni náà ni láti san owo ti ó fi tọ́jú ara rẹ̀ padà fún un, lẹ́yìn ìgbà tí ara rẹ̀ bá ti yá tan pátápátá.

20. “Bí ọkùnrin kan bá fi ọ̀pá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrubìnrin rẹ̀, ti ẹrú náà sì kú lójú ẹṣẹ̀, a ó fi ìyà jẹẹ́.

21. Ṣùgbọ́n a kò ní fi ìyà jẹ̀ ẹ́, ti ẹrú náà bá yè, tí ó dìde lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí méjì, nítorí ẹrú náà jẹ́ dúkìá rẹ̀.

22. “Bí àwọn ènìyàn ti ń jà bá pa aboyún lára, tí aboyún náà bá bimọ láìpé ọjọ́, ṣùgbọ́n ti kò sí aburú mìíràn mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ẹni ti ó fa ìpalára yìí yóò san iyekíye ti ọkọ aboyún náà bá béèrè fún, bí ilé ẹjọ́ bá se gbà láàyè gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.

23. Ṣùgbọ́n bí ìpalára náà bá yọrí sí ikú aboyún náà, pípa ni a ó pa ẹni ti ó fa ikú aboyún náà.

24. Ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹṣẹ̀ fún ẹṣẹ̀,

25. ìjóná fún ìjóná, ọgbẹ́ fún ọgbẹ́, ìnà fún ìnà.

26. “Bí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, ti ojú náà sì fọ́, ó ni láti jẹ́ kí ẹrú náà lọ ní òmìnira fún ìtanràn ojú rẹ̀ ti ó fọ́.

27. Bí ó bá sì lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ti eyín rẹ̀ fi ká, ó ni láti jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira ni ìtanran fún eyín rẹ̀ tí ó ká.

28. “Bí akọ màlúù bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò ní dá ẹni tí ó ni akọ màlúù náà lẹ́bi, ọrùn rẹ̀ yóò sì mọ́.

29. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo ti akọ màlúù náà ti máa ń kan ènìyàn, tí a sì ti ń kìlọ̀ fún olówó rẹ̀, ti olówó rẹ̀ kò sì mú un so, tí ó bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a ó sì pa olówó rẹ̀ pẹ̀lú.

30. Bí àwọn ará ilé ẹni tí ó kú bá béèrè fún owó ìtanràn, yóò san iye owó tí wọ́n bá ní kí ó san fún owó ìtanràn láti fi ra ẹ̀mí araarẹ̀ padà.

31. Bí akọ màlúù bá kan ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin pa, a ó se gẹ́gẹ́ bí ofin yìí ti là á kalẹ̀.

32. Bí akọ màlúù bá kan ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin pa, olówó rẹ̀ yóò san ọgbọ̀n sékélì fàdákà fún ẹni tó ni ẹrú, a ó sì sọ akọ màlúù náà ni okúta pa.

33. “Bí ọkùnrin kan bá sí kòtò sílẹ̀ láìbò tàbí kí ó gbẹ́ kòtò sílẹ̀ láìbò, tí màlúù tàbi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá se bẹ́ẹ̀ bọ́ sínú kòtò náà.

34. Ẹni tí ó ni kòtò yóò san owó àdánù yìí fún ẹni tí ó ni ẹran. Òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 21