Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 21:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Wọ̀nyí ni àwọn òfin tí ìwọ yóò gbé sí iwájú wọn:

2. “Bí ìwọ bá yá ọkùnrin Hébérù ní ìwẹ̀fà, òun yóò sìn ọ́ fún ọdún Mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, òun yóò lọ ni òmìnira láìsan ohunkóhun padà.

3. Bí ó bá wá ní òun nìkan òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira; ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ.

4. Bí olówó rẹ̀ bá fún un ní aya, tí aya náà sì bímọ ọkùnrin àti obìnrin, aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ ti olówó rẹ̀, yóò sì lọ ní òmìnira ní òun nìkan.

5. “Bí ìwọ̀fà náà bá sọ gbangba pé, mo fẹ́ràn olówó mi, ìyàwó mi àti àwọn mi èmi kò sì fẹ́ ẹ́ gba òmíràn mọ́:

6. Nígbà náà ni olówó rẹ̀ yóò mu wá sí iwájú ìdàjọ́. Òun yóò sì mú un lọ sí ẹnu ọ̀nà tàbí lọ sí ibi òpó, yóò sì fi ìlutí lu etí rẹ̀, òun yóò sì máa sin olówó rẹ̀ títí ayé.

7. “Bí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ bí ìwẹ̀fà, ọmọbìnrin yìí kò ní gba òmìnìra bí i ti ọmọkùnrin.

8. Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àwọn èniyàn orílẹ̀ èdè mìíràn, nítorí pé òun ni kò se ojúse rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà.

9. Bí ó bá fẹ́ ẹ fún ọmọkùnrin rẹ̀, kò ní máa lò ó bí ìwẹ̀fà mọ́, ṣùgbọ́n yóò máa ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ obìnrin.

10. Bí ó bá fẹ́ obìnrin mìíràn, kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ nípa fífún un ní oúnjẹ àti aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ sí aya.

11. Bí ó bá kùnà láti ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí fún un, òun yóò lọ ní òmìnira láìsan owó kankan padà.

12. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu arákùnrin rẹ̀ pa, pípa ni a ó pa á.

13. Ṣùgbọ́n bí kò bá mọ̀ ọ́n mọ̀ pa á, tí ó bá jẹ́ (àmúwá) ìfẹ́ Ọlọ́run ni, òun yóò lọ sí ibi tí èmi yóò yàn fún un.

Ka pipe ipin Ékísódù 21