Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 20:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé:

2. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì, jáde ni oko ẹrú.

3. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.

4. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara rẹ ní àwòrán ohun kóhun tí ń bẹ ní òkè ọ̀run tàbí tí ń bẹ ní ayé, tàbí tí ń bẹ ní ìṣàlẹ̀ omi.

5. Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀sẹ̀ baba wò lára ọmọ láti ìran kìn-ín-ní títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.

Ka pipe ipin Ékísódù 20