Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 20:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé:

2. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì, jáde ni oko ẹrú.

3. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.

4. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara rẹ ní àwòrán ohun kóhun tí ń bẹ ní òkè ọ̀run tàbí tí ń bẹ ní ayé, tàbí tí ń bẹ ní ìṣàlẹ̀ omi.

Ka pipe ipin Ékísódù 20