Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 19:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Réfídímù, wọ́n wọ ijù Ṣínáì, wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀ ní iwájú òkè Ṣínáì.

3. Mósè sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. Olúwa sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jákọ́bù àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:

4. ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Éjíbítì, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì.

5. Nísinsìn yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́rán sí mi dé ojú àmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mu mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀ èdè yóòkù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi.

6. Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀ èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”

7. Mósè sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbààgbà láàárin àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti Olúwa pàṣẹ fún un láti sọ ni iwájú wọn.

8. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò se ohun gbogbo ti Olúwa wí.” Mósè sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ.

9. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu síṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mósè sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún Olúwa.

10. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn.

Ka pipe ipin Ékísódù 19