Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 19:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mósè sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn.

20. Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì, o sì pe Mósè wá sí orí òkè náà. Mósè sì gun orí òkè.

21. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo Olúwa, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé.

22. Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá ṣíwájú Olúwa gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. Olúwa yóò kọ lù wọ́n.”

23. Mósè wí fún Olúwa pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Ṣínáì, nítorí ìwọ fúnrarẹ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ”

24. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Árónì gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ Olúwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.”

25. Mósè ṣọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ. Ó sì sọ ohun tí Olúwa wí fún wọn.

Ka pipe ipin Ékísódù 19