Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 19:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Mósè sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè.

18. Èéfín sì bo òkè Sínáì nítorí Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná. Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì.

19. Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mósè sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn.

20. Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì, o sì pe Mósè wá sí orí òkè náà. Mósè sì gun orí òkè.

21. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo Olúwa, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé.

22. Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá ṣíwájú Olúwa gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. Olúwa yóò kọ lù wọ́n.”

23. Mósè wí fún Olúwa pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Ṣínáì, nítorí ìwọ fúnrarẹ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ”

Ka pipe ipin Ékísódù 19