Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 16:28-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́?

29. Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni ounjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọọkan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.”

30. Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.

31. Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sì pe oúnjẹ náà ní Mánà. Ó funfun bí irúgbìn kóríáńdà, ó sì dùn bí burẹ́dì fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe.

32. Mósè wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì mánà kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì.’ ”

33. Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó mánà tí ó kún òṣùnwọ̀n ómérì kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú Olúwa láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.”

34. Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè, Árónì gbé mánà sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́.

Ka pipe ipin Ékísódù 16