Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 15:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin yìí sí Olúwa:Èmi yóò kọrin sí Olúwa,nítorí òun pọ̀ ní ògo.Ẹsin àti ẹni tí ó gùn unni ó ti sọ sínú òkun.

2. Olúwa ni agbára àti orin mi;òun ti di Olùgbàlà mi,òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín,Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.

3. Ologun ni Olúwa, Olúwa ni orúkọ rẹ,

4. Kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti ogun rẹ̀ni ó mú wọ inú òkun.Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáfáfá jùlọni ó rì sínú òkun pupa.

5. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;Wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.

6. “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,pọ̀ ní agbára.Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,fọ́ àwọn ọ̀ta túútúú.

7. Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbiìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;Tí ó run wọ́n bí ìgémọ́lẹ̀ ìdí koríko

8. Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ńwọ́jọ pọ̀Ìsàn omi dìde dúró bí odi;Ibú omi sì dìpọ̀ láàrin òkun.

Ka pipe ipin Ékísódù 15