Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 15:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin yìí sí Olúwa:Èmi yóò kọrin sí Olúwa,nítorí òun pọ̀ ní ògo.Ẹsin àti ẹni tí ó gùn unni ó ti sọ sínú òkun.

2. Olúwa ni agbára àti orin mi;òun ti di Olùgbàlà mi,òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín,Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.

3. Ologun ni Olúwa, Olúwa ni orúkọ rẹ,

4. Kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti ogun rẹ̀ni ó mú wọ inú òkun.Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáfáfá jùlọni ó rì sínú òkun pupa.

5. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;Wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.

6. “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,pọ̀ ní agbára.Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,fọ́ àwọn ọ̀ta túútúú.

7. Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbiìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;Tí ó run wọ́n bí ìgémọ́lẹ̀ ìdí koríko

8. Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ńwọ́jọ pọ̀Ìsàn omi dìde dúró bí odi;Ibú omi sì dìpọ̀ láàrin òkun.

9. “Ọ̀ta ń gbéraga, ó ń wí pé:‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn.Èmi ó pín ìkógun;Èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn.Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’

10. Ìwọ fẹ́ èèmí rẹòkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀wọ́n rì bí òjéni àárin omi ńlá.

11. “Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, Olúwa?Ta ló dàbí rẹ:ní títóbi,ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìnTí ń se ohun ìyanu?

12. Ìwọ na apá ọ̀tún rẹIlẹ̀ si gbé wọn mì.

13. “Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í ṣákìíìwọ se amọ̀nàÀwọn ènìyàn náà tí ìwọ ti ràpadàNínú agbára rẹ ìwọ yóò tọ́ wọn lọsí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.

14. Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrìÌkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn palẹ́sítínì.

Ka pipe ipin Ékísódù 15