Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 10:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Fáráò, mo ti ṣé ọkàn Fáráò le àti ọkàn àwọn ìjòyè rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn.

2. Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yin àti àwọn ọmọ ọmọ yín; Bí mo ti jẹ àwọn ará Éjíbítì níyà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn. Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

3. Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, ti wọn sí wí fún pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn Hébérù sọ: ‘Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi?

4. Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn lọ, èmi yóò mú eṣú wa sí orílẹ̀-èdè rẹ ní ọ̀la.

5. Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀. Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ.

6. Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Éjíbítì. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mósè pẹ̀yìndà kúrò níwájú Fáráò.

7. Àwọn ìjòyè Fáráò sọ fún “Yóò ti pẹ to tí ọkùnrin yìí yóò máa mú ìyọnu bá wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí ṣíbẹ̀ pé, ilẹ̀ Éjíbítì ti parun tán?”

Ka pipe ipin Ékísódù 10