Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 1:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ọba Éjíbítì sọ fún àwọn agbẹ̀bí Hébérù ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣífúrà àti Púà pé:

16. “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Hébérù, tí ẹ sì kíyèsí wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láàyè.”

17. Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Éjíbítì ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láàyè.

Ka pipe ipin Ékísódù 1