Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 1:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá Jákọ́bù lọ sí Éjíbítì, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀:

2. Rúbẹ́nì, Símónì, Léfì àti Júdà,

3. Ísákárì, Ṣébúlúnì àti Bẹ́ńjámínì,

4. Dánì àti Náfítalì, Gádì àti Ásérì.

5. Àwọn ìran Jákọ́bù sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Jóṣẹ́fù sì ti wà ní Éjíbítì.

6. Wáyìí o, Jóṣẹ́fù àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú,

7. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì ń bí sí i, wọ́n ń pọ̀ sí i gidigidi, wọ́n kò sì ní òǹkà tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kún ilẹ̀ náà.

8. Nígbà náà ni ọba túntún ti kò mọ nípa Jósẹ́fù jẹ ní ilẹ̀ Éjíbítì.

9. Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ “Ẹ wò ó, àwọn ará Ísírẹ́lì ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa.

10. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.”

11. Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pítómi àti Ráméṣéṣì gẹ́gẹ́ bí ìlú ìkó ìṣúra pamọ́ sí fún Fáráò.

12. Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, ti wọn sì ń tàn kálẹ̀; Nítorí náà, àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rù nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì.

13. Wọ́n sì mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekú láìkáánú wọn.

Ka pipe ipin Ékísódù 1