Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 6:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ẹ kọ wọ́n sára àwọn férémù ìlẹ̀kùn àwọn ilé yín àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde yín.

10. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú ọ dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín: Fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù láti fi fún un yín, Ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ,

11. àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kàǹga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso ólífì tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n: Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó,

12. ẹ sọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa, tí o mú un yín jáde láti Éjíbítì wá, kúrò ní oko ẹrú.

13. Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan.

14. Ẹ má ṣe tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká;

15. torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà.

16. Ẹ má ṣe dán Olúwa Ọlọ́run yín wò bí ẹ ti ṣe ní Máṣà.

17. Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín.

18. Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú Olúwa, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.

19. Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀ta yín jáde níwájú u yín bí Olúwa ti ṣèlérí.

Ka pipe ipin Deutarónómì 6