Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 6:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín.

18. Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú Olúwa, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.

19. Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀ta yín jáde níwájú u yín bí Olúwa ti ṣèlérí.

20. Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?”

21. Sọ fún un pé: “Ẹrú Fáráò ní ilẹ̀ Éjíbítì ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Éjíbítì.

22. Lójú wa ni Olúwa tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Éjíbítì àti Fáráò, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀.

23. Ṣùgbọ́n ó mú wa jáde láti ibẹ̀ wá láti mú wa wọ inú àti láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wa.

24. Olúwa pàṣẹ fún wa láti ṣe ìgbọ́ran sí gbogbo ìlànà wọ̀nyí, làti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, kí ó báà lè má a dára fún wa nígbà gbogbo, kí a sì lè wà láyé, bí a se wà títí di òní.

Ka pipe ipin Deutarónómì 6