Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 4:8-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Orílẹ̀ èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

9. Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì sọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láàyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.

10. Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Hórébù, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ ṣíwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”

11. Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí ẹ sì dúró ní ẹṣẹ̀ òkè náà, nígbà tí òkè náà yọná lala lọ sókè ọrun pẹ̀lú ìkúùkù ńlá, àti òkùnkùn biribiri.

12. Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárin iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́.

13. Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí sílétì òkúta méjì.

14. Olúwa sọ fún mi nígbà tí ẹ gbọdọ̀ tẹ̀lée, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ ìní yín lẹ́yìn tí ẹ bá la Jọ́dánì kọjá.

15. Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárin iná wá. Torí náà ẹ sọ́ra yín gidigidi,

16. kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin,

17. tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò lófuurufú,

18. tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi.

19. Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ débi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀ èdè lábẹ́ ọ̀run.

Ka pipe ipin Deutarónómì 4