Deutarónómì 4:9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì sọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láàyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.