Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 4:17-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò lófuurufú,

18. tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi.

19. Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ débi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀ èdè lábẹ́ ọ̀run.

20. Olúwa Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ị́jíbítì, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí.

21. Inú Olúwa ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí Olúwa Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín.

22. Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdì kejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà.

23. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá: Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí.

24. Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.

25. Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́: Bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yòówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú.

26. Mo pe ọ̀run àti ayé láti jẹ́rìí takò yín lónìí, pé kíákíá ni ẹ ó parun ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń la Jọ́dánì kọjá lọ láti gbà. Ẹ kò ní pẹ́ ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò run pátapáta.

27. Olúwa yóò fọ́n-ọn yín ká sí àárin àwọn ènìyàn náà, àwọn díẹ̀ nínú un yín ni yóò yè láàrin orílẹ̀ èdè tí Olúwa yóò fọ́n ọn yín sí.

28. Ẹ ó sì máa sin Ọlọ́run tí àwọn ènìyàn fi ọwọ́ ṣe: tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe, èyí tí kò le ríran, gbọ́rọ̀, jẹun tàbí gbọ́ òórùn.

29. Bí ẹ̀yin bá wá Olúwa Ọlọ́run yín láti bẹ̀ẹ́ ẹ ó ri i, bí ẹ bá wá a, pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà a yín.

30. Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ Olúwa Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀.

31. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra.

32. Ẹ bèèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ bèèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkì báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí?

33. Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè?

34. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀ èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnra rẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína ọwọ́, tàbí nípa iṣẹ́ ipá àti agbára ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Éjíbítì ní ojú ẹ̀yin tìká ara yín?

35. A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀.

36. Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní aye, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárin iná wá,

Ka pipe ipin Deutarónómì 4