Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́ Ísírẹ́lì, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín.

2. Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, Ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.

3. Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Olúwa ṣe ní Báálí-Péórì. Olúwa Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Báálì ti Péórì kúrò ní àárin yín.

4. Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láàyè lónìí.

Ka pipe ipin Deutarónómì 4