Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 34:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò débẹ̀.”

5. Bẹ́ẹ̀ ni Mósè ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Móábù, bí Olúwa ti wí.

6. Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Móábù, tí ó kọjú sí Béhì-Péórì, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnì kan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà.

Ka pipe ipin Deutarónómì 34