Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 32:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,Jákọ́bù ni ìpín ìní i rẹ̀.

10. Ní ihà ni ó ti rí i,ní ihà níbi tí ẹranko kò sí.Ó yíká, ó sì tọ́jú u rẹ̀,ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.

11. Bí idì ti íru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ńrábàbà sórí ọmọ rẹ̀,tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sìgbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.

12. Olúwa samọ̀nà;kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.

13. Ó mú gun ibi gíga ayéó sì fi èṣo oko bọ́ ọ.Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,àti òróró láti inú akọ òkúta wá,

14. Pẹ̀lú u wàràǹkàsì àti wàrà àgùntànàti ti àgbò ẹranàti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́ àgùntàn àti ewúrẹ́,pẹ̀lú àgbò irú u ti Báṣánìtí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èṣo-àjàrà, àní àti wáìnì.

15. Jéṣúrúnì sanra tán ó sì tàpá;ìwọ ṣanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọo sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.

16. Wọ́n sì fi jowú pẹ̀lú ọlọ́run àjèjì i wọnwọ́n sì mú un bínú pẹ̀lú àwọn òrìṣà a wọn.

17. Wọ́n rúbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,ọlọ́run tí ó sẹ̀sẹ̀ farahàn láìpẹ́,ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.

18. Ìwọ kò rántí Àpáta, tí ó bí ọ;o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.

19. Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,nítorí tí ó ti bínú nítori ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ìn rẹ.

20. Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn.

Ka pipe ipin Deutarónómì 32