Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 32:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Wọ́n sì fi jowú pẹ̀lú ọlọ́run àjèjì i wọnwọ́n sì mú un bínú pẹ̀lú àwọn òrìṣà a wọn.

17. Wọ́n rúbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,ọlọ́run tí ó sẹ̀sẹ̀ farahàn láìpẹ́,ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.

18. Ìwọ kò rántí Àpáta, tí ó bí ọ;o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.

19. Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,nítorí tí ó ti bínú nítori ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ìn rẹ.

20. Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn.

21. Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,wọ́n sì fi ohun aṣán an wọn mú mi bínú.Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀ èdè.

22. Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú un mi,yóò sì jó dé ipò ikú ní ìṣàlẹ̀.Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

23. “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.

24. Èmi yóò mú wọn gbẹ,ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.

25. Idà ní òde,àti ìpayà nínú ìyẹ̀wù.Ni yóò run ọmọkùnrin àti wúndíá,ọmọ ẹnu-ọmú àti arúgbó eléwù irun pẹ̀lú.

26. Mo ní èmi yóò tú wọn káèmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúró nínú àwọn ènìyàn,

27. nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀ta,kí àwọn ọ̀ta a wọn kí ó mába à wí pé, ‘Ọwọ́ ọ wa lékè ni;kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”

28. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè tí kò ní ìmọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú un wọn.

29. Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọnkí wọn ròbí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí!

30. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún,tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàaàrún sá,bí kò ṣe pé Àpáta wọn ti tà wọ́n,bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?

Ka pipe ipin Deutarónómì 32