Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 31:22-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nígbà náà ni Móṣè kọ orin yìí kalẹ̀ ní ọjọ́ náà ó sì kọ ọ́ sí Ísírẹ́lì.

23. Olúwa sì fún Jósúà ọmọ Núnì ní àṣẹ yìí: “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí ìwọ yóò mú Ísírẹ́lì wá sí ilẹ̀ tí mo ṣèlérí fún wọn lórí ìbúra, èmi fúnra à mi yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ.”

24. Lẹ́yìn ìgbà tí Móṣè ti parí i kíkọ ọ̀rọ̀ òfin yìí sínú ìwé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin,

25. ó sì fi àṣẹ yìí fún àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń gbé àpótí i májẹ̀mú Olúwa:

26. “Gba ìwé òfin yìí kí o sì fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí i májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run rẹ. Níbẹ̀ ni yóò wà bí ẹ̀rí sí ọ.

27. Nítorí mo mọ irú ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́rùn líle tí ẹ jẹ́. Bí o bá ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí Olúwa nígbà tí mo pàpà wà láyé Pẹ̀lú u yín, báwo ní ẹ ó ti ṣe ọlọ̀tẹ̀ tó nígbà tí mo bá kú tan!

28. Ẹ péjọ pọ̀ ṣíwájú ù mi gbogbo àgbà ẹ̀yà yín àti àwọn aláṣẹ yín, kí èmi lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí etíìgbọ́ ọ́ wọn.

29. Nítorí tí mo mọ̀ pé lẹ́yìn ikú mi, ó dájú pé ìwọ yóò padà di ìbàjẹ́ pátápátá, ẹ ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pa láṣẹ fún un yín. Ní ọjọ́ tó ń bọ̀, ìpọ́njú yóò sọ̀kalẹ̀ sórí i yín nítorí ẹ̀yin yóò ṣe búburú níwájú Olúwa ẹ ó sì mú u bínú nípa ohun tí ọwọ́ ọ yín ti ṣe.”

30. Móṣè sì ka ọ̀rọ̀ inú orin yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin sí etí ìgbọ́ ọ gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì:

Ka pipe ipin Deutarónómì 31