Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 3:7-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀ṣìn àti ìkógún àwọn ìlú wọn, fún ara wa.

8. Ní ìgbà náà ni a ti gba ilẹ̀ tí ó wà ní Jọ́dánì láti odò Ánónì, títí dé orí òkè Hámónì lọ́wọ́ àwọn ọba Ámórì méjèèjì wọ̀nyí.

9. (Àwọn ará Sídónì ń pe Hámónì ní Sírónì: Àwọn Ámórì sì ń pè é ní Sénírì)

10. Gbogbo àwọn ìlú tí o wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gílíádì, àti gbogbo Báṣánì, títí dé Ṣálékà, àti Édíréì, ìlú àwọn ọba Ógù ní ilẹ̀ Báṣánì.

11. (Ógù tí í ṣe ọba Báṣánì nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Ráfátì. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rábà ti àwọn Ámórì.)

12. Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Áréórì níbi odò Ánónì, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gílíádì pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.

13. Gbogbo ìyókù Gílíádì àti gbogbo Básánì, ní ilẹ̀ ọba Ógù ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè. (Gbogbo agbégbé Ágóbù ni Básánì tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Ráfátì.

14. Jáérì ọ̀kan nínú àwọn ìran Mánásè gba gbogbo agbégbé Ágóbù títí dé ààlà àwọn ará Gésúrì àti àwọn ará Mákátì; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Básánì fi ń jẹ́ Hafoti-Jáírì títí di òní.)

15. Mo sì fi Gílíádì fún Mákírì,

16. ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti Gádì ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gílíádì lọ dé odò Ánónì (àárin odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jábókù. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ámónì.

17. Apá ìwọ̀ óòrùn rẹ̀ ni Jọ́dánì, ní aginjù, láti Kínérétì títí dé òkun aginjù (Tí í ṣe òkun iyọ̀) ní ihà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.

18. Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “Olúwa Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ni ín. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá ṣíwájú àwọn arákùnrin yín: ará Ísírẹ́lì.

19. Àwọn ẹ̀yà a yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ohun ọ̀sìn in yín (Mo mọ̀ pé ẹ ti ní ohun ọ̀sìn púpọ̀) lè dúró ní àwọn ìlú tí mo fi fún un yín,

20. títí di ìgbà tí Olúwa yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jọ́dánì. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.”

21. Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Jósúà pé, “Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ.

22. Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, Olúwa Ọlọ́run yín tìkálára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín.”

23. Nígbà náà ni mo bẹ Olúwa wí pé,

24. “Ọlọ́run Alágbára, ìwọ tí ń fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ. Ọlọ́run wo ló tó bẹ́ẹ̀ láyé àti lọ́run tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tí o ti ṣe?

25. Jẹ́ kí n kọjá lọ wo ilẹ̀ rere ti ìkọjá Jọ́dánì: Ilẹ̀ òkè dídára nì àti Lẹ́bánónì.”

26. Ṣùgbọ́n torí i ti yín, Olúwa Ọlọ́run bínú sí mi kò sì gbọ́ tèmi. Olúwa sọ wí pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí sí mi mọ́.

Ka pipe ipin Deutarónómì 3