Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 3:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn èyí ní a yípadà tí a sì kọrí sí ọ̀nà tí ó lọ sí Báṣánì, Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ ṣígun wá pàdé wa ní Édíréì.

2. Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù u rẹ̀ torí pé mo ti fi lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀. Bí ẹ tí ṣe sí Ṣíhónì ọba Ámórì, tí ó jọba ní Héṣíbónì ni kí ẹ ṣe sí i.”

3. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wa fi Ógù ọba Báṣánì àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. A pa wọ́n run láìṣẹ́ku ẹnì kankan.

4. Ní ìgbà náà ní a gba gbogbo àwọn ìlú rẹ̀. Kò sí ọ̀kankan tí a kò gbà nínú àwọn ọgọta (60) ìlú tí wọ́n ní: Gbogbo agbégbé Ágóbù, lábẹ́ ìjọba Ógù ní Báṣánì.

5. Gbogbo ìlú wọ̀nyí ní a mọ odi gíga yíká pẹ̀lú àwọn ìlẹ̀kùn àti irin. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú kékèké tí a kò mọ odi yíká sì tún wà pẹ̀lú.

6. Gbogbo wọn ni a parun pátapáta gẹ́gẹ́ bí á ti ṣe sí Síhónì ọba Hésíbónì, tí a pa gbogbo ìlú wọn run pátapáta: tọkùnrin tobìnrin àti àwọn ọmọ wọn.

7. Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀ṣìn àti ìkógún àwọn ìlú wọn, fún ara wa.

8. Ní ìgbà náà ni a ti gba ilẹ̀ tí ó wà ní Jọ́dánì láti odò Ánónì, títí dé orí òkè Hámónì lọ́wọ́ àwọn ọba Ámórì méjèèjì wọ̀nyí.

9. (Àwọn ará Sídónì ń pe Hámónì ní Sírónì: Àwọn Ámórì sì ń pè é ní Sénírì)

10. Gbogbo àwọn ìlú tí o wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gílíádì, àti gbogbo Báṣánì, títí dé Ṣálékà, àti Édíréì, ìlú àwọn ọba Ógù ní ilẹ̀ Báṣánì.

11. (Ógù tí í ṣe ọba Báṣánì nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Ráfátì. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rábà ti àwọn Ámórì.)

12. Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Áréórì níbi odò Ánónì, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gílíádì pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.

13. Gbogbo ìyókù Gílíádì àti gbogbo Básánì, ní ilẹ̀ ọba Ógù ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè. (Gbogbo agbégbé Ágóbù ni Básánì tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Ráfátì.

14. Jáérì ọ̀kan nínú àwọn ìran Mánásè gba gbogbo agbégbé Ágóbù títí dé ààlà àwọn ará Gésúrì àti àwọn ará Mákátì; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Básánì fi ń jẹ́ Hafoti-Jáírì títí di òní.)

Ka pipe ipin Deutarónómì 3