Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 28:49-67 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. Olúwa yóò mú àwọn orílẹ̀ èdè wá sí ọ láti ọ̀nà jínjìn, bí òpin ayé, bí idì ti ń bẹ́ láti orí òkè sílẹ̀, orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè wọn.

50. Orílẹ̀ èdè tí ó rorò tí kò ní ojúrere fún àgbà tàbí àánú fún ọmọdé.

51. Wọn yóò jẹ ohun ọ̀sìn rẹ run àti àwọn èṣo ilẹ̀ rẹ títí tí ìwọ yóò fi parun. Wọn kì yóò fi hóró irúgbìn kan fún ọ, wáìnì túntún tàbí òróró, tàbí agbo ẹran màlúù rẹ kankan tàbí ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn rẹ títí ìwọ yóò fi run.

52. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ.

53. Nítorí ìyà tí ọ̀ta à rẹ yóò fi jẹ ọ́ nígbà ìgbógun tì, ìwọ yóò jẹ, ẹran ara ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí Olúwa Ọlọ́run ti fi fún ọ.

54. Ènìyàn jẹ́jẹ́ àti onímọ̀ jùlọ kò ní ní àánú fún arákùnrin ara rẹ̀ tàbí ìyàwó tí ó fẹ́ràn tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ tí o wà láàyè,

55. Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìpọ́njú tí àwọn ọ̀ta yóò fi pọ́n ọ lójú ní ìlú u rẹ.

56. Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú u yín, tí ó si ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹṣẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà a rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin

57. ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí láti inú u rẹ̀ àti àwọn ọmọ tí ó ti bí. Nítorí ó fẹ́ láti jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀ nígbà ìgbógun tì àti ní ìgbà ìpọ́njú tí ọ̀ta rẹ yóò fi jẹ ọ́ nínú àwọn ìlú rẹ.

58. Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ,

59. Olúwa yóò rán ìyọnu tí ó ní ìbẹ̀rù sórí rẹ, àti sórí irú ọmọ ọ̀ rẹ, àti àwọn àjálù pípẹ́, àti ìmúna àti àìsàn ìlọ́ra.

60. Olúwa yóò mú gbogbo àrùn Éjíbítì tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá sórí ì rẹ, wọn yóò sì so mọ́ ọ.

61. Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ÌWÉ ÒFIN yìí wá sórí ì rẹ, títí ìwọ yóò fi run.

62. Ìwọ tí ó dàbí àìmòye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò sẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.

63. Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

64. Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.

65. Ìwọ kì yóò sinmi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹ́ṣẹ̀ rẹ. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà.

66. Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rù-bojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ.

67. Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ níkan ni!” nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí.

Ka pipe ipin Deutarónómì 28