Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 28:39-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ́ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èṣo jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run.

40. Ìwọ yóò ní igi ólífì jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí ólífì náà yóò rẹ̀ dànù.

41. Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò ní pa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

42. Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ.

43. Àlejò tí ń gbé láàrin rẹ yóò gbé sókè gíga jù ọ́ lọ, ṣùgbọ́n ìwọ yóò máa di ìrẹ̀sílẹ̀.

44. Yóò yà ọ́, ṣùgbọ́n o kì yóò yà á, òun ni yóò jẹ́ orí, ìwọ yóò jẹ́ ìrù.

45. Gbogbo ègun yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsí àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ.

46. Wọn yóò jẹ́ àmì àti ìyanu fún ọ àti fún irú ọmọ rẹ títí láé.

47. Nítorí ìwọ kò sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ní ayọ̀ àti inú dídùn ní àkókò àlàáfíà.

48. Nítorí náà nínú ebi àti òùngbẹ, nínú ìhòòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀ta à rẹ tí Olúwa rán sí ọ. Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́.

49. Olúwa yóò mú àwọn orílẹ̀ èdè wá sí ọ láti ọ̀nà jínjìn, bí òpin ayé, bí idì ti ń bẹ́ láti orí òkè sílẹ̀, orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè wọn.

50. Orílẹ̀ èdè tí ó rorò tí kò ní ojúrere fún àgbà tàbí àánú fún ọmọdé.

51. Wọn yóò jẹ ohun ọ̀sìn rẹ run àti àwọn èṣo ilẹ̀ rẹ títí tí ìwọ yóò fi parun. Wọn kì yóò fi hóró irúgbìn kan fún ọ, wáìnì túntún tàbí òróró, tàbí agbo ẹran màlúù rẹ kankan tàbí ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn rẹ títí ìwọ yóò fi run.

52. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ.

Ka pipe ipin Deutarónómì 28