Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 28:35-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Olúwa yóò lu eékún àti ẹṣẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ́lẹṣẹ̀ méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ.

36. Olúwa yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lóríì rẹ lọ sí orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbi ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta.

37. Ìwọ yóò padà wá di ohun ìbẹ̀rù àti ohun ẹ̀gàn àti ẹlẹ́yà sí gbogbo orílẹ̀ èdè tí Olúwa yóò lé ọ lọ.

38. Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ̀ ẹ́ run.

Ka pipe ipin Deutarónómì 28