Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 26:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí o sì ti ń gbé níbẹ̀,

2. mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèṣè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé.

3. Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé “Mo sọ ọ́ di mímọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.”

4. Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ.

5. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Árámíà, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀ èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.

6. Ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá níyà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe.

7. Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa.

8. Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Éjíbítì pẹ̀lu ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu.

9. Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin;

Ka pipe ipin Deutarónómì 26