Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 23:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ ènìyàn wá.

2. Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹwàá.

3. Kí Ámónì tàbí Móábù tàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wọn má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹ̀wàá.

4. Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Éjíbítì àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégún Bálámù ọmọ Béórì ará a Pétórì ti Árámù Náháráímù.

5. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Bálámù ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ.

6. Má ṣe wá ìpinnu ìbádọ́rẹ́ pẹ̀lú u wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láàyè.

7. Má ṣe kórìíra ará Édómù kan nítorí arákùnrin rẹ ni. Má se kórìíra ará Éjíbítì, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àléjò ní ilẹ̀ rẹ̀.

8. Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa.

9. Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀ta rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò.

10. Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́.

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.

Ka pipe ipin Deutarónómì 23