Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 20:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má baà wá tún dáyà fò ó.”

9. Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀.

10. Nígbà tí ó bá sún mọ́ iwájú láti dojú kọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́.

11. Tí wọ́n bá gbà tí wọ́n sì sí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́.

12. Tí wọ́n bá kọ̀ láti bá ọ ṣe àlàáfíà ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbógun tì ọ́, nígbà náà ni kí ìwọ gbà á.

13. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́, ẹ pa gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà níbẹ̀.

14. Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógún fún ara rẹ. O sì lè lo ìkógún tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta rẹ.

15. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo ìlú tí wọ́n wà ní ọ̀nà jínjìn sí ọ tí wọn kò sì tara àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ rẹ.

Ka pipe ipin Deutarónómì 20