Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 20:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀ta rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì, yóò wà pẹ̀lú rẹ.

2. Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá ṣíwájú, yóò sì bá ọmọ ogun sọ̀rọ̀,

3. yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀ta rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi àyè fún ìjayà níwájú u wọn.

4. Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ó ń lọ pẹ̀lú rẹ láti jà fún ọ kí ó sì fún ọ ní ìṣẹgun.”

5. Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé túntún tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú ṣójú ogun kí elòmìíràn sì gbà á.

6. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmìíràn sì gbádùn rẹ̀.

7. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹẹ? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹẹ́.”

Ka pipe ipin Deutarónómì 20