Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 20:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀ta rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì, yóò wà pẹ̀lú rẹ.

2. Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá ṣíwájú, yóò sì bá ọmọ ogun sọ̀rọ̀,

3. yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀ta rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi àyè fún ìjayà níwájú u wọn.

Ka pipe ipin Deutarónómì 20