Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 2:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn ará Hórì gbé ní Séírì kí àwọn ọmọ Ísọ̀ tó lé wọn kúrò níwájú wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, (wọ́n tẹ̀dó sí àyè wọn) gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ṣe ní ilẹ̀ tí Olúwa yóò fún wọn ní ìní wọn.

13. Olúwa sì wí pé, “Ẹ dìde, kí ẹ sì la àfonífojì Sérádì kọjá.” Bẹ́ẹ̀ ni a la àfonífojì náà kọjá.

14. Ó gbà wá ní ọdún méjìdínlógójì (38) kí ó tó di wí pé a la àfonífojì Sérédì kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní Kadesi Báníyà. Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrin àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrin àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí Olúwa ti búra fún wọn.

15. Ọwọ́ Olúwa sì wà lára wọn fún ibi títí gbogbo wọn fi run tan nínú ibùdó.

16. Lẹ́yìn tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn pátapáta nínú àwọn jagunjagun àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti kú,

17. Olúwa sọ fún mi pé,

18. “Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbégbé Móábù kọjá ní Árì.

19. Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ámónì, ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ámónì fún un yín ní ìní. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọ́tì ní ìní.”

20. (A ka ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ àwọn Réfáímù, tí wọ́n ti gbé níbẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ará Ámónì ń pè wọ́n ní Sámúsúmímù.

21. Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tó lágbára, wọ́n sì pọ̀, wọ́n sì ga gògòrò bí àwọn ará Ánákì. Olúwa run wọn kúrò níwájú àwọn ará Ámónì, tí wọ́n lé wọn jáde tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.

Ka pipe ipin Deutarónómì 2