Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí ihà, a gba ọ̀nà òkun pupa, bí Olúwa ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Séírì.

2. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé,

3. “Ẹ ti rìn yí agbégbé ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá.

4. Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Ísọ̀; àwọn ará Édómù tí ń gbé ní Séírì. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi.

Ka pipe ipin Deutarónómì 2