Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 18:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, àní gbogbo ẹ̀yà Léfì, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrin Ísírẹ́lì, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa, nítorí òun ni ogún un tiwọn.

2. Wọn kì yóò ní ìní láàrin àwọn arákùnrin wọn; Ọlọ́run ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti se ìlérí fún wọn.

3. Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rúbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà.

4. Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn.

5. Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa títí láé.

6. Tí ọmọ Léfì kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Ísírẹ́lì, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí Ọlọ́run yóò yàn.

7. Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú Olúwa níbẹ̀.

8. Wọn yóò ní ìpín kan láti jẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gba owó nípa títa ogún baba rẹ̀.

9. Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀ èdè náà tí ó wà níbẹ̀.

10. Má se jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rúbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ ṣe àyẹ̀wò, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́,

Ka pipe ipin Deutarónómì 18