Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 16:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

7. Ẹ ṣun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín.

8. Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fí jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ kéje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.

9. Ka ọ̀ṣẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà.

10. Nígbà náà ni kí ẹ se àjọ̀dún ọ̀ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèṣè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.

11. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrú u yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn Léfì tí ó wà ní ìlú u yín, àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárin yín.

12. Ẹ rántí pé ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára.

13. Ẹ ṣe ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti kórè oko yín tí ẹ ti pakà tí ẹ sì ti fún ọtí tán.

Ka pipe ipin Deutarónómì 16