Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 16:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi se ayẹyẹ fún Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún.

16. Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún ni gbogbo àwọn ènìyàn an yín gbọdọ̀ farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn. Níbi àpèjẹ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀ṣẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ wá ṣíwájú Olúwa lọ́wọ́ òfo.

17. Olúkúlùkù u yín gbọdọ̀ mú ẹ̀bùn wá bí Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún fún un tó.

18. Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.

19. Ẹ má ṣe yí ẹjọ́ po, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe ojúṣàájú. Ẹ má ṣe gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọgbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ òdodo jẹ́.

20. Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ báà lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín.

21. Ẹ má ṣe ri òpó òrìṣà áṣérà ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tí ẹ ti mọ fún Olúwa Ọlọ́run yín.

22. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé òkúta òrìṣà gbígbẹ́ kan kalẹ̀ fún ara yín, nítorí èyí ni Olúwa Ọlọ́run yín kórìíra.

Ka pipe ipin Deutarónómì 16