Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 14:24-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Bí ibẹ̀ bá jìn tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí Olúwa yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù).

25. Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sówó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí Olúwa yóò yàn.

26. Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú Olúwa níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀.

27. Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Léfì tí ó ń gbé nì ilú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í se tiwọn.

28. Ní òpin ọdún mẹ́tamẹ́ta, ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá irè oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín.

29. Kí àwọn Léfì (tí kò ní ìpín tàbí ogún ti wọn) àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí Olúwa Ọlọ́run rẹ leè bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

Ka pipe ipin Deutarónómì 14