Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 12:12-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́-bìnrin àti ìránṣẹ́-kùnrin yín, àti àwọn Léfì láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn.

13. Ẹ sọ́ra kí ẹ má ṣe rú ẹbọ siṣun yín ní ibikíbi tí ẹ̀yin fẹ́.

14. Ibi tí Olúwa yóò yàn láàrin àwọn ẹ̀yà a yín nìkan ni kí ẹ ti máa rú ẹbọ yín, kí ẹ sì máa kíyèsí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín níbẹ̀.

15. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ẹ lọ pa àwọn ẹran yín ní èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín, kí ẹ sì jẹ ẹran náà tó bí ẹ ti fẹ́, bí ẹ ti ń ṣe sí àgbọ̀nrín àti èṣúó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run yín tí ó fi fún un yín, àti ẹni mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ nínú àwọn ẹran náà.

16. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, ẹ dàá sílẹ̀ bí omi.

17. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àkọ́bí àwọn màlúù yín, tàbí ti ewúrẹ́ ẹ yín, ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ àtinúwá, tàbí ẹ̀bùn pàtàkì ní ìlú ẹ̀yin tìkárayín.

18. Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín, yóò yàn: ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin rẹ àti àwọn Léfì láti ìlú u yín: kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín.

19. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Léfì, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ń gbé ní ilẹ̀ ẹ yín.

20. Bí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti fẹ́ agbègbè e yín bí ó ti ṣe ìlérí, fún un yín, tí ẹ sì wí pé, àwa yóò jẹ ẹran, nítorí tí ọkàn wa fẹ́ jẹran. Ẹ jẹ ẹran náà bí ẹ tí fẹ́.

21. Bí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín bá yàn fún orúkọ rẹ̀ bá jìnnà sí i yín, kí ẹ pa màlúù tàbí ewúrẹ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fún un yín, bí mo ti pàṣẹ fún un yín ní ìlú u yín, ẹ lè jẹ ẹ́ bí ẹ ti fẹ́.

22. Ẹ jẹ wọ́n bí ẹ ó ti jẹ èṣúó tàbí àgbọ̀nrín, ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́.

23. Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀mí pọ̀ mọ́ ẹran.

24. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

25. Ẹ má ṣe jẹ ẹ́, kí ó báà lè dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín, tí ń bọ̀ lẹ́yìn in yín. Nígbà yí ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà lójú Olúwa.

26. Ẹ mú àwọn ohun tí ẹ yà sọ́tọ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ́ yín, kí ẹ sì lọ síbi tí Olúwa yóò yàn.

Ka pipe ipin Deutarónómì 12