Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 11:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tíì mọ̀.

29. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín ba ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gérísímù, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ébálì.

30. Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jọ́dánì ní apá ìwọ̀ oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igbó igi Mórè ńlá, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kénánì, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbégbé Gígálì.

31. Ẹ ti ṣetan láti la Jọ́dánì kọjá láti lè gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á, tí ẹ bá sì ń gbé ibẹ̀,

32. ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń gbọ́ran sí gbogbo ìlànà àti òfin tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

Ka pipe ipin Deutarónómì 11