Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 1:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nígbà náà ni èmi yóò ṣọ ohun tí ẹ ó ṣe fún un yín.

19. Nígbà náà ní a gbé ra láti Horebu, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wá, a sì la àwọn ilẹ̀ lókè Ámórì kọjá lọ dé gbogbo aṣálẹ̀ ńlá tí ó ba ni lẹ́rù nì tí ẹ̀yin ti rí, bẹ́ẹ̀ ni a sì dé Kádésì Báníyà.

20. Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ ti dé ilẹ̀ òkè àwọn ará Ámórì, èyí tí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.

21. Ẹ kíyèsìí, Olúwa Ọlọ́run yín ló ní ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, Ẹ má sì ṣe fòyà.”

22. Nígbà náà ni gbogbo yín tọ̀ mí wá wí pé, “Jẹ́ kí a yan àwọn ayọ́lẹ̀wò láti yọ́ ilẹ̀ náà wò fún wa, kí wọn sì fún wa ní ìròyìn àwọn ọ̀nà tí a ó gbà àti àwọn ìlú tí a ó bá pàdé.”

23. Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

24. Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ésíkónì, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò.

25. Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

26. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ; ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín.

27. Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “Olúwa kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Éjíbítì láti fi wá lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́ láti pa wá run.

28. Níbo la ó lọ? Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, ‘Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ; àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run. A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán (Ará Ánákì) níbẹ̀.’ ”

29. Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn.

Ka pipe ipin Deutarónómì 1